Add parallel Print Page Options

Àwọn onírúurú òfin

19 Olúwa sọ fún Mose pé, (A)“Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.

(B)“ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

(C)“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

(D)“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

11 (E)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.

12 (F)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.

13 (G)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.

14 (H)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.

15 (I)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.

16 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

18 (J)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

19 (K)“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.

“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira. 21 Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa. 22 Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.

23 “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ 24 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa. 25 Ní ọdún karùn-ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

26 (L)“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.

27 (M)“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.

28 “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.

29 (N)“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.

30 (O)“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa.

31 (P)“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

32 “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni Olúwa.

33 (Q)“ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi 34 kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

35 (R)“ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. 36 Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.

37 “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”

Various Laws

19 The Lord said to Moses, “Speak to the entire assembly of Israel(A) and say to them: ‘Be holy because I, the Lord your God,(B) am holy.(C)

“‘Each of you must respect your mother and father,(D) and you must observe my Sabbaths.(E) I am the Lord your God.(F)

“‘Do not turn to idols or make metal gods for yourselves.(G) I am the Lord your God.(H)

“‘When you sacrifice a fellowship offering to the Lord, sacrifice it in such a way that it will be accepted on your behalf. It shall be eaten on the day you sacrifice it or on the next day; anything left over until the third day must be burned up.(I) If any of it is eaten on the third day, it is impure and will not be accepted.(J) Whoever eats it will be held responsible(K) because they have desecrated what is holy(L) to the Lord; they must be cut off from their people.(M)

“‘When you reap the harvest of your land, do not reap to the very edges(N) of your field or gather the gleanings of your harvest.(O) 10 Do not go over your vineyard a second time(P) or pick up the grapes that have fallen.(Q) Leave them for the poor and the foreigner.(R) I am the Lord your God.

11 “‘Do not steal.(S)

“‘Do not lie.(T)

“‘Do not deceive one another.(U)

12 “‘Do not swear falsely(V) by my name(W) and so profane(X) the name of your God. I am the Lord.

13 “‘Do not defraud or rob(Y) your neighbor.(Z)

“‘Do not hold back the wages of a hired worker(AA) overnight.(AB)

14 “‘Do not curse the deaf or put a stumbling block in front of the blind,(AC) but fear your God.(AD) I am the Lord.

15 “‘Do not pervert justice;(AE) do not show partiality(AF) to the poor or favoritism to the great,(AG) but judge your neighbor fairly.(AH)

16 “‘Do not go about spreading slander(AI) among your people.

“‘Do not do anything that endangers your neighbor’s life.(AJ) I am the Lord.

17 “‘Do not hate a fellow Israelite in your heart.(AK) Rebuke your neighbor frankly(AL) so you will not share in their guilt.

18 “‘Do not seek revenge(AM) or bear a grudge(AN) against anyone among your people,(AO) but love your neighbor(AP) as yourself.(AQ) I am the Lord.

19 “‘Keep my decrees.(AR)

“‘Do not mate different kinds of animals.

“‘Do not plant your field with two kinds of seed.(AS)

“‘Do not wear clothing woven of two kinds of material.(AT)

20 “‘If a man sleeps with a female slave who is promised to another man(AU) but who has not been ransomed or given her freedom, there must be due punishment.[a] Yet they are not to be put to death, because she had not been freed. 21 The man, however, must bring a ram to the entrance to the tent of meeting for a guilt offering to the Lord.(AV) 22 With the ram of the guilt offering the priest is to make atonement for him before the Lord for the sin he has committed, and his sin will be forgiven.(AW)

23 “‘When you enter the land and plant any kind of fruit tree, regard its fruit as forbidden.[b] For three years you are to consider it forbidden[c]; it must not be eaten. 24 In the fourth year all its fruit will be holy,(AX) an offering of praise to the Lord. 25 But in the fifth year you may eat its fruit. In this way your harvest will be increased. I am the Lord your God.

26 “‘Do not eat any meat with the blood still in it.(AY)

“‘Do not practice divination(AZ) or seek omens.(BA)

27 “‘Do not cut the hair at the sides of your head or clip off the edges of your beard.(BB)

28 “‘Do not cut(BC) your bodies for the dead or put tattoo marks on yourselves. I am the Lord.

29 “‘Do not degrade your daughter by making her a prostitute,(BD) or the land will turn to prostitution and be filled with wickedness.(BE)

30 “‘Observe my Sabbaths(BF) and have reverence for my sanctuary. I am the Lord.(BG)

31 “‘Do not turn to mediums(BH) or seek out spiritists,(BI) for you will be defiled by them. I am the Lord your God.

32 “‘Stand up in the presence of the aged, show respect(BJ) for the elderly(BK) and revere your God.(BL) I am the Lord.(BM)

33 “‘When a foreigner resides among you in your land, do not mistreat them. 34 The foreigner residing among you must be treated as your native-born.(BN) Love them as yourself,(BO) for you were foreigners(BP) in Egypt.(BQ) I am the Lord your God.

35 “‘Do not use dishonest standards when measuring length, weight or quantity.(BR) 36 Use honest scales(BS) and honest weights, an honest ephah[d](BT) and an honest hin.[e](BU) I am the Lord your God, who brought you out of Egypt.(BV)

37 “‘Keep all my decrees(BW) and all my laws(BX) and follow them. I am the Lord.’”

Footnotes

  1. Leviticus 19:20 Or be an inquiry
  2. Leviticus 19:23 Hebrew uncircumcised
  3. Leviticus 19:23 Hebrew uncircumcised
  4. Leviticus 19:36 An ephah was a dry measure having the capacity of about 3/5 of a bushel or about 22 liters.
  5. Leviticus 19:36 A hin was a liquid measure having the capacity of about 1 gallon or about 3.8 liters.

19 And the Lord spake unto Moses, saying,

Speak unto all the congregation of the children of Israel, and say unto them, Ye shall be holy: for I the Lord your God am holy.

Ye shall fear every man his mother, and his father, and keep my sabbaths: I am the Lord your God.

Turn ye not unto idols, nor make to yourselves molten gods: I am the Lord your God.

And if ye offer a sacrifice of peace offerings unto the Lord, ye shall offer it at your own will.

It shall be eaten the same day ye offer it, and on the morrow: and if ought remain until the third day, it shall be burnt in the fire.

And if it be eaten at all on the third day, it is abominable; it shall not be accepted.

Therefore every one that eateth it shall bear his iniquity, because he hath profaned the hallowed thing of the Lord: and that soul shall be cut off from among his people.

And when ye reap the harvest of your land, thou shalt not wholly reap the corners of thy field, neither shalt thou gather the gleanings of thy harvest.

10 And thou shalt not glean thy vineyard, neither shalt thou gather every grape of thy vineyard; thou shalt leave them for the poor and stranger: I am the Lord your God.

11 Ye shall not steal, neither deal falsely, neither lie one to another.

12 And ye shall not swear by my name falsely, neither shalt thou profane the name of thy God: I am the Lord.

13 Thou shalt not defraud thy neighbour, neither rob him: the wages of him that is hired shall not abide with thee all night until the morning.

14 Thou shalt not curse the deaf, nor put a stumblingblock before the blind, but shalt fear thy God: I am the Lord.

15 Ye shall do no unrighteousness in judgment: thou shalt not respect the person of the poor, nor honor the person of the mighty: but in righteousness shalt thou judge thy neighbour.

16 Thou shalt not go up and down as a talebearer among thy people: neither shalt thou stand against the blood of thy neighbour; I am the Lord.

17 Thou shalt not hate thy brother in thine heart: thou shalt in any wise rebuke thy neighbour, and not suffer sin upon him.

18 Thou shalt not avenge, nor bear any grudge against the children of thy people, but thou shalt love thy neighbour as thyself: I am the Lord.

19 Ye shall keep my statutes. Thou shalt not let thy cattle gender with a diverse kind: thou shalt not sow thy field with mingled seed: neither shall a garment mingled of linen and woollen come upon thee.

20 And whosoever lieth carnally with a woman, that is a bondmaid, betrothed to an husband, and not at all redeemed, nor freedom given her; she shall be scourged; they shall not be put to death, because she was not free.

21 And he shall bring his trespass offering unto the Lord, unto the door of the tabernacle of the congregation, even a ram for a trespass offering.

22 And the priest shall make an atonement for him with the ram of the trespass offering before the Lord for his sin which he hath done: and the sin which he hath done shall be forgiven him.

23 And when ye shall come into the land, and shall have planted all manner of trees for food, then ye shall count the fruit thereof as uncircumcised: three years shall it be as uncircumcised unto you: it shall not be eaten of.

24 But in the fourth year all the fruit thereof shall be holy to praise the Lord withal.

25 And in the fifth year shall ye eat of the fruit thereof, that it may yield unto you the increase thereof: I am the Lord your God.

26 Ye shall not eat any thing with the blood: neither shall ye use enchantment, nor observe times.

27 Ye shall not round the corners of your heads, neither shalt thou mar the corners of thy beard.

28 Ye shall not make any cuttings in your flesh for the dead, nor print any marks upon you: I am the Lord.

29 Do not prostitute thy daughter, to cause her to be a whore; lest the land fall to whoredom, and the land become full of wickedness.

30 Ye shall keep my sabbaths, and reverence my sanctuary: I am the Lord.

31 Regard not them that have familiar spirits, neither seek after wizards, to be defiled by them: I am the Lord your God.

32 Thou shalt rise up before the hoary head, and honour the face of the old man, and fear thy God: I am the Lord.

33 And if a stranger sojourn with thee in your land, ye shall not vex him.

34 But the stranger that dwelleth with you shall be unto you as one born among you, and thou shalt love him as thyself; for ye were strangers in the land of Egypt: I am the Lord your God.

35 Ye shall do no unrighteousness in judgment, in meteyard, in weight, or in measure.

36 Just balances, just weights, a just ephah, and a just hin, shall ye have: I am the Lord your God, which brought you out of the land of Egypt.

37 Therefore shall ye observe all my statutes, and all my judgments, and do them: I am the Lord.