Add parallel Print Page Options

13 (A)Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ: ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. 14 Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. 15 O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. 16 Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.

Read full chapter

10 Ìwọ̀n èké àti òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ
    Olúwa kórìíra méjèèjì.

Read full chapter

10 Kí ẹ̀yin kì ó lo òṣùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́.

Read full chapter