Add parallel Print Page Options

(A)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

Read full chapter

Èrè ìgbọ́ràn

26 (A)‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

Read full chapter

Èèwọ̀ ni ìbọ̀rìṣà jẹ́

15 Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Horebu láti àárín iná wá. Torí náà ẹ ṣọ́ra yín gidigidi, 16 kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin, 17 tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò ní òfúrufú, 18 tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi. 19 Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.

Read full chapter

15 (A)“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

Read full chapter