Add parallel Print Page Options

Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn

21 (A)Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 22 (B)Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 (C)Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24 Jesu sì ń bá a lọ.

Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

Read full chapter

35 Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.

36 Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”

37 (A)Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39 Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40 Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.

Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 41 (B)Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42 Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43 (C)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.

Read full chapter

Ikú Lasaru

11 (A)Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. (B)Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”

(C)Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún Ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.”

(D)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?”

(E)Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.”

11 (F)Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ: lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.”

12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀: ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn.

14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. 15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.”

16 (G)Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.”

Jesu tu àwọn arábìnrin rẹ̀ nínú

17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 Ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún: 19 (H)Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé.

21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24 (I)Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25 (J)Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè: 26 (K)Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27 (L)Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 30 Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀. 31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.

32 (M)Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”

33 Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. 34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”

Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”

35 (N)Jesu sọkún.

36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”

37 (O)Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?”

Jesu jí òkú Lasaru dìde

38 (P)Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”

Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.”

40 Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?”

41 (Q)Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. 42 (R)Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”

43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” 44 (S)Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.

Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!”

Read full chapter

17 Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú. 18 (A)Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?”

19 Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀. 20 Nígbà náà ni ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?” 21 Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”

22 Olúwa sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí. 23 Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!”

24 Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ẹnu rẹ.”

Read full chapter

32 Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. 33 Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 34 Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná. 35 Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀.

36 Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” 37 Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

Read full chapter