Add parallel Print Page Options

22 (A)Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. 23 (B)Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”

Read full chapter

26 (A)(B) “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.

Read full chapter

(A)Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.

Read full chapter

13 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni.

Read full chapter