Luku 11:14-15
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu àti Beelsebulu
14 (A)(B) Ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn. 15 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Beelsebulu olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
Read full chapter
Matiu 12:22-24
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu àti Beelsebulu
22 (A)(B) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”
24 (C)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
Read full chapter
Marku 3:22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 (A)(B) Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”
Read full chapter
Johanu 7:20
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
20 (A)Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.