Add parallel Print Page Options

Jesu àti Beelsebulu

22 (A)(B) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”

24 (C)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

25 Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. 28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.

29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.

30 (D)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká.

Read full chapter

25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

Read full chapter

23 Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? 24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. 25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. 26 Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. 27 (A)Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀.

Read full chapter