Add parallel Print Page Options

38 (A)Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 39 Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. 40 Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn: Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi.

Read full chapter

(A)Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,

“Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí,
    tí Èmi yóò bá ilé Israẹli
    àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú
    tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,
nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde
    kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi
èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí
10 Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli
    dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.
Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,
    èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,
èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,
    wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
11 Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,
    tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’
Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,
    láti kékeré dé àgbà.
12 Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn,
    àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”

Read full chapter

16 (A)“Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá
    lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.
Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn,
    inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

17 Ó tún sọ wí pé:

“Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn
    lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”

Read full chapter