Add parallel Print Page Options

Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.

Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
    Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
    Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.

Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
    Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
    ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
    Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
    Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
    àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.

Olúwa jẹ ọba títí láé;
    ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
(A)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
    yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
    ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
    nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
    kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
    òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
    Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
    ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
    àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.

15 Àwọn orílẹ̀-èdè ti jì sí kòtò tí wọn ti gbẹ́;
    ẹsẹ̀ wọn ni àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ kọ́.
16 A mọ Olúwa nípa òdodo rẹ̀;
    àwọn ènìyàn búburú ni a dẹ́kun mú nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
17 Àwọn ènìyàn búburú ni a ó dà sí isà òkú,
    àti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọ́run.
18 Ṣùgbọ́n àwọn aláìní ni a kò ní gbàgbé láéláé,
    ìrètí àwọn ti ó tálákà ni a kì yóò gbàgbé láéláé.

19 Dìde, Olúwa, má ṣe jẹ́ kí ènìyàn borí;
    Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ni iwájú rẹ.
20 Lù wọ́n pẹ̀lú ìpayà, Olúwa;
    jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ènìyàn lásán ni wọ́n. Sela.