Add parallel Print Page Options

137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
    àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
    tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
    tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
    ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

Àwa ó ti ṣe kọ orin
    Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
    jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
    olórí ayọ̀ mi gbogbo.

Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
    lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
    “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
    ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
    bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
    tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.