Add parallel Print Page Options

28 Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: 29 Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. 30 Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31 aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú:

Read full chapter

19 (A)Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20 Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21 Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

Read full chapter