Add parallel Print Page Options

22 Láti ìran Simeoni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 23 Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbàá-mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (59,300).

24 Láti ìran Gadi:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn. 25 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gadi jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).

26 Láti ìran Juda:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 27 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlógójì ó-lé-ẹgbẹ̀ta (74,600).

28 Láti ìran Isakari:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 29 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (54,400).

30 Láti ìran Sebuluni:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 31 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (57,400).

32 Láti inú àwọn ọmọ Josẹfu:

Láti ìran Efraimu:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 33 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Efraimu jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

34 Láti ìran Manase:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 35 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Manase jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún ó-lé-igba (32,200).

36 Láti ìran Benjamini:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 37 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Benjamini jẹ́ ẹgbàá-mẹ́tà-dínlógún ó-lé-egbèje (35,400).

38 Láti ìran Dani:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 39 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).

40 Láti ìran Aṣeri:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 41 Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).

42 Láti ìran Naftali:

Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 43 Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Naftali jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

44 Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mose àti Aaroni kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Israẹli, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣojú fún ìdílé rẹ̀. 45 Gbogbo ọmọkùnrin Israẹli tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. 46 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-egbéjì-dínlógún-dínàádọ́ta, (603,550).

Read full chapter