Add parallel Print Page Options

Ìkọ̀sílẹ̀

31 (A)“A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ 32 Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

Read full chapter

Mo sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, ó ṣe panṣágà.”

Read full chapter

11 (A)Jesu túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó. 12 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”

Read full chapter

10 Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11 Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.

Read full chapter