Add parallel Print Page Options

Jesu ṣe ìwòsàn

23 (A)Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Read full chapter

44 (A)Ó sì ń wàásù nínú Sinagọgu ti Judea.

Read full chapter