Add parallel Print Page Options

Àwọn olùṣọ́ ní ibojì

62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (A)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”

65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (B)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.

Read full chapter