Add parallel Print Page Options

20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.

21 (A)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”

Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”

22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”

Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”

Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

Read full chapter

11 (A)Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà ru ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè pé, kí ó kúkú dá Baraba sílẹ̀ fún wọn.

12 Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?”

13 Wọ́n sì tún kígbe sókè pé, “Kàn án mọ àgbélébùú!”

14 Nígbà náà ni Pilatu bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?”

Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

Read full chapter

13 (A)Ọlọ́run Abrahamu, àti Isaaki, àti Jakọbu, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jesu ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pilatu, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀. 14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣẹ́ Ẹni Mímọ́ àti Olóòótọ́ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.

Read full chapter

38 (A)Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá: nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”

40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.

Read full chapter

14 (A)Ó jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ àjọ ìrékọjá, ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí ẹ̀kẹfà:

Ó sì wí fún àwọn Júù pé, “Ẹ wo ọba yín!”

15 Nítorí náà wọ́n kígbe wí pé, “Mú un kúrò, mú un kúrò. Kàn án mọ́ àgbélébùú.”

Pilatu wí fún wọn pé, “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́ àgbélébùú bí?”

Àwọn olórí àlùfáà dáhùn wí pé, “Àwa kò ní ọba bí kò ṣe Kesari.”

Read full chapter