Add parallel Print Page Options

44 “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé,
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
títí tí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ
    sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ.” ’

Read full chapter

64 (A)Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”

Read full chapter

36 (A)Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

Read full chapter

62 (A)Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”

Read full chapter

19 Nígbà tí Jesu Olúwa sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ báyìí tan, á gbé e lọ sí ọ̀run, ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

Read full chapter

42 Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé:

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43 títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’

Read full chapter

69 Ṣùgbọ́n láti ìsinsin yìí lọ ni Ọmọ ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”

Read full chapter

34 (A)Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkára rẹ̀ wí pé,

“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
    “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

Read full chapter

25 (A)Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

Read full chapter

20 (A)èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run.

Read full chapter

Àwọn òfin fún ìgbé ayé ìwà mímọ́

(A)Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.

Read full chapter

Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.

Read full chapter

13 (A)Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,

“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?

Read full chapter

12 (A)Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; 13 Láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.

Read full chapter

(A)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

Read full chapter