Matiu 21:15-16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹmpili pé, “Hosana fún ọmọ Dafidi,” inú bí wọn.
16 (B)Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”
Jesu sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”
“Àbí ẹ̀yin kò kà á pé ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọmú,
ni a ó ti máa yìn mí?’ ”
Heberu 2:11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.