Add parallel Print Page Options

Ẹ̀bẹ̀ ìyá

20 (A)(B) Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.

21 (C)Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”

22 (D)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?”

Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”

23 (E)Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”

24 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí. 25 (F)Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba. 26 Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, 27 Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin. 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”

Read full chapter