Add parallel Print Page Options

20 (A)Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.”

Read full chapter

Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn musitadi, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi sikamine yìí pé, ‘di fi fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú Òkun,’ yóò sì gbọ́ tiyín.

Read full chapter

(A)Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.

Read full chapter

Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá béèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyèméjì dàbí ìgbì omi Òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

Read full chapter