Add parallel Print Page Options

14 (A)Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́
    etí wọn sì wúwo láti gbọ́
    ojú wọn ni wọ́n sì dì
nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí
    kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́
    kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’

Read full chapter

12 (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,

“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”

Read full chapter

10 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni a fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn wọn yóò jẹ́ òwe, pé ní rí rí,

“ ‘kí wọn má ba à rí,
    àti ní gbígbọ́ kí ó má lè yé wọn.’

Read full chapter

39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé:

40 (A)“Ó ti fọ́ wọn lójú,
    Ó sì ti sé àyà wọn le;
kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
    kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
    kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”

41 (B)Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

Read full chapter

26 (A)‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,
“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    à ti ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ẹ̀yin kì yóò sí wòye.”
27 Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,
    etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,
    ojú wọn ni wọn sì ti di.
Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,
    kí wọn kí ó má ba à fi etí wọn gbọ́,
    àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,
kí wọn kí ó má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

Read full chapter