Add parallel Print Page Options

Àkọsílẹ̀ ìwé ìran Jesu Kristi

Ìwé ìran Jesu Kristi, ẹni tí í ṣe ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu:

Abrahamu ni baba Isaaki;

Isaaki ni baba Jakọbu;

Jakọbu ni baba Juda àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

Juda ni baba Peresi àti Sera,

Tamari sì ni ìyá rẹ̀,

Peresi ni baba Hesroni:

Hesroni ni baba Ramu;

Ramu ni baba Amminadabu;

Amminadabu ni baba Nahiṣoni;

Nahiṣoni ni baba Salmoni;

Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀;

Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀;

Obedi sì ni baba Jese;

Jese ni baba Dafidi ọba.

Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

Solomoni ni baba Rehoboamu,

Rehoboamu ni baba Abijah,

Abijah ni baba Asa,

Asa ni baba Jehoṣafati;

Jehoṣafati ni baba Jehoramu;

Jehoramu ni baba Ussiah;

Ussiah ni baba Jotamu;

Jotamu ni baba Ahaṣi;

Ahaṣi ni baba Hesekiah;

10 Hesekiah ni baba Manase;

Manase ni baba Amoni;

Amoni ni baba Josiah;

11 (A)Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

12 Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli:

Jekoniah ni baba Ṣealitieli;

Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

13 Serubbabeli ni baba Abihudi;

Abihudi ni baba Eliakimu;

Eliakimu ni baba Asori;

14 Asori ni baba Sadoku;

Sadoku ni baba Akimu;

Akimu ni baba Elihudi;

15 Elihudi ni baba Eleasari;

Eleasari ni baba Mattani;

Mattani ni baba Jakọbu;

16 Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Abrahamu dé orí Dafidi, ìran mẹ́rìnlá á láti orí Dafidi títí dé ìkólọ sí Babeli, àti ìran mẹ́rìnlá láti ìkólọ títí dé orí Kristi.

Ìtàn ibí Jesu Kristi

18 (B)Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. 19 Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

20 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni. 21 (C)Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

22 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ èyí tí a sọ láti ẹnu wòlíì rẹ̀ wá pé: 23 (D)“Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” èyí tí ó túmọ̀ sí, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”

24 Nígbà tí Josẹfu jí lójú oorun rẹ̀, òun ṣe gẹ́gẹ́ bí angẹli Olúwa ti pàṣẹ fún un. Ó mú Maria wá sílé rẹ̀ ní aya. 25 Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ ọ́n títí tí ó fi bí ọmọkùnrin, òun sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu.

The Genealogy of Jesus the Messiah(A)(B)(C)

This is the genealogy[a] of Jesus the Messiah[b] the son of David,(D) the son of Abraham:(E)

Abraham was the father of Isaac,(F)

Isaac the father of Jacob,(G)

Jacob the father of Judah and his brothers,(H)

Judah the father of Perez and Zerah, whose mother was Tamar,(I)

Perez the father of Hezron,

Hezron the father of Ram,

Ram the father of Amminadab,

Amminadab the father of Nahshon,

Nahshon the father of Salmon,

Salmon the father of Boaz, whose mother was Rahab,(J)

Boaz the father of Obed, whose mother was Ruth,

Obed the father of Jesse,

and Jesse the father of King David.(K)

David was the father of Solomon, whose mother had been Uriah’s wife,(L)

Solomon the father of Rehoboam,

Rehoboam the father of Abijah,

Abijah the father of Asa,

Asa the father of Jehoshaphat,

Jehoshaphat the father of Jehoram,

Jehoram the father of Uzziah,

Uzziah the father of Jotham,

Jotham the father of Ahaz,

Ahaz the father of Hezekiah,

10 Hezekiah the father of Manasseh,(M)

Manasseh the father of Amon,

Amon the father of Josiah,

11 and Josiah the father of Jeconiah[c] and his brothers at the time of the exile to Babylon.(N)

12 After the exile to Babylon:

Jeconiah was the father of Shealtiel,(O)

Shealtiel the father of Zerubbabel,(P)

13 Zerubbabel the father of Abihud,

Abihud the father of Eliakim,

Eliakim the father of Azor,

14 Azor the father of Zadok,

Zadok the father of Akim,

Akim the father of Elihud,

15 Elihud the father of Eleazar,

Eleazar the father of Matthan,

Matthan the father of Jacob,

16 and Jacob the father of Joseph, the husband of Mary,(Q) and Mary was the mother of Jesus who is called the Messiah.(R)

17 Thus there were fourteen generations in all from Abraham to David, fourteen from David to the exile to Babylon, and fourteen from the exile to the Messiah.

Joseph Accepts Jesus as His Son

18 This is how the birth of Jesus the Messiah came about[d]: His mother Mary was pledged to be married to Joseph, but before they came together, she was found to be pregnant through the Holy Spirit.(S) 19 Because Joseph her husband was faithful to the law, and yet[e] did not want to expose her to public disgrace, he had in mind to divorce(T) her quietly.

20 But after he had considered this, an angel(U) of the Lord appeared to him in a dream(V) and said, “Joseph son of David, do not be afraid to take Mary home as your wife, because what is conceived in her is from the Holy Spirit. 21 She will give birth to a son, and you are to give him the name Jesus,[f](W) because he will save his people from their sins.”(X)

22 All this took place to fulfill(Y) what the Lord had said through the prophet: 23 “The virgin will conceive and give birth to a son, and they will call him Immanuel”[g](Z) (which means “God with us”).

24 When Joseph woke up, he did what the angel(AA) of the Lord had commanded him and took Mary home as his wife. 25 But he did not consummate their marriage until she gave birth to a son. And he gave him the name Jesus.(AB)

Footnotes

  1. Matthew 1:1 Or is an account of the origin
  2. Matthew 1:1 Or Jesus Christ. Messiah (Hebrew) and Christ (Greek) both mean Anointed One; also in verse 18.
  3. Matthew 1:11 That is, Jehoiachin; also in verse 12
  4. Matthew 1:18 Or The origin of Jesus the Messiah was like this
  5. Matthew 1:19 Or was a righteous man and
  6. Matthew 1:21 Jesus is the Greek form of Joshua, which means the Lord saves.
  7. Matthew 1:23 Isaiah 7:14