Marku 15:21
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú
21 (A)Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Simoni ará Kirene. Òun ni baba Aleksanderu àti Rufusi. Wọ́n sì mú un ní tipátipá, pé kí ó rú àgbélébùú Jesu.
Read full chapter
Luku 23:26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú
26 (A)Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Simoni ara Kirene, tí ó ń ti ìgbèríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélébùú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jesu.
Read full chapter
Johanu 19:17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
17 (A)Nítorí náà, wọ́n mú Jesu, ó sì jáde lọ, ó ru àgbélébùú fúnrarẹ̀ sí ibi tí à ń pè ní ibi agbárí, ní èdè Heberu tí à ń pè ní Gọlgọta:
Read full chapter
Heberu 13:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.