Add parallel Print Page Options

13 (A)Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apá kejì Òkun náà.

Ìwúkàrà àwọn Farisi àti Herodu

14 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú àkàrà tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù àkàrà kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn. 15 (B)Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”

16 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrín ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni?”

17 (C)Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? 19 (D)Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?”

Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

20 (E)“Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”

21 Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”

Read full chapter