Add parallel Print Page Options

Àjíǹde

16 (A)(B) Nígbà tí ọjọ́ ìsinmi sì kọjá, Maria Magdalene, Maria ìyá Jakọbu, àti Salome mú òróró olóòórùn dídùn wá kí wọn bá à le fi kun Jesu lára.

Read full chapter

Òwe afúnrúgbìn kan

(A)Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, Àti àwọn obìnrin kan, tí a ti mú láradá kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí búburú àti nínú àìlera wọn, Maria tí a ń pè ní Magdalene, lára ẹni tí ẹ̀mí èṣù méje ti jáde kúrò. Àti Joanna aya Kuṣa tí í ṣe ìríjú Herodu, àti Susana, àti àwọn púpọ̀ mìíràn, tí wọ́n ń ṣe ìránṣẹ́ fún un nínú ohun ìní wọn.

Read full chapter

Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

Read full chapter