Add parallel Print Page Options

Òwe àwọn ayálégbé

12 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.

“Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’

“Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.

“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10 (B)Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
    òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
    ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”

12 (C)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.

Read full chapter

Òwe àwọn ayálégbé

(A)(B) Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́. 10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 11 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’

14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’ 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.

“Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn? 16 (C)Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”

17 (D)Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?

18 (E)Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

19 (F)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

Read full chapter

Orin ọgbà àjàrà náà

(A)Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
    orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀;
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
    ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
    ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
    ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
    ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
    àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
    ọgbà àjàrà mi.
Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
    Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
    èéṣe tí ó fi so kíkan?
Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
    ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi:
Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
    a ó sì pa á run,
Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
    yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
    láì kọ ọ́ láì ro ó,
ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
    Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
    láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ni ilé Israẹli
àwọn ọkùnrin Juda
    sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí,
    Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

Read full chapter