Luku 22:18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
18 (A)Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”
Read full chapter
Matiu 10:23
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.
Read full chapter
1 Tẹsalonika 4:15-18
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
15 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa, pé àwa tí ó wà láààyè, tí a sì kù lẹ́yìn de à ti wá Olúwa, bí ó ti wù kí ó rí, kì yóò ṣáájú àwọn tí ó sùn láti pàdé rẹ̀. 16 (A)Nítorí pé, Olúwa fúnrarẹ̀ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn angẹli ti àwọn angẹli ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kristi yóò sì kọ́kọ́ jíǹde. 17 Nígbà náà ni a ó gba àwa tí ó sì wà láààyè sókè nínú àwọsánmọ̀ láti ọwọ́ Olúwa. A ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ títí láéláé. 18 Nítorí náà, ẹ tu ara yín nínú, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
Read full chapter
Johanu 21:22
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 (A)Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.