Add parallel Print Page Options

(A)Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti Nasareti ni Galili, sí ìlú Dafidi ní Judea, tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé Dafidi ní í ṣe, láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Maria aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.

Read full chapter

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi

(A)Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti.

Read full chapter