Add parallel Print Page Options

Má ṣe ṣe àníyàn

22 (A) Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. 23 Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. 24 (B)Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! 25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?

27 (C)“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. 30 (D)Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. 31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.

Read full chapter

41 (A)Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀.

Read full chapter

11 (A)“Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí:

Read full chapter

(A)Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.

Read full chapter

(A)Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

Read full chapter