Add parallel Print Page Options

24 (A)“Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, ‘Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.’ 25 Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 26 Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkára rẹ̀ lọ wá: wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀: ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”

Read full chapter

20 Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ.

Read full chapter