Add parallel Print Page Options

26 Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.

Read full chapter

27 Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó gé ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

Read full chapter

10 (A)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11 Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.

13 “ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.

Read full chapter

16 (A)Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

Read full chapter

23 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ wọn, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀mí pọ̀ mọ́ ẹran.

Read full chapter