Add parallel Print Page Options

30 (A)“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. 32 Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa. 33 Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”

Read full chapter

21 “Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé 22 Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú 23 Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 24 Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn: Wọn kò nígba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.”

25 Olúwa sọ fún Mose pé, 26 “Sọ fún àwọn ọmọ Lefi kí o sì wí fún wọn pé: ‘Nígbà tí ìdámẹ́wàá bá ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ. O gbọdọ̀ mú ìdámẹ́wàá lára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Olúwa. 27 A ó ka ọrẹ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọkà irúgbìn láti ilẹ̀ ìpakà tàbí wáìnì láti fún wa. 28 Báyìí ni ìwọ gan an náà yóò mú ọrẹ wa fún Olúwa láti ara ìdámẹ́wàá tí ìwọ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli. Láti ara ìdámẹ́wàá ó gbọdọ̀ mú ọrẹ Olúwa fún Aaroni àlùfáà. 29 Ìwọ gbọdọ̀ mú wá gẹ́gẹ́ bí ìpín Olúwa èyí tí ó dára jùlọ àti tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ lára gbogbo nǹkan tí wọ́n mú wá fún ọ.’

30 “Sọ fún àwọn ọmọ pé: ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá mú ìpín tí ó dára jù wá, a ó kà á sí fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ìkórè láti ilẹ̀ ìpakà tàbí ìfúntí yín. 31 Ìwọ àti àwọn ìdílé rẹ̀ le jẹ èyí tí ó kù ní ibikíbi gbogbo. Nítorí pé ó jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ rẹ níbi àgọ́ ìpàdé. 32 Nípa ṣíṣe ìgbékalẹ̀ ìpín tí ó dára jùlọ o kò ní jẹ̀bi lórí ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ kò sì ní ba ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli jẹ́, ìwọ kì yóò sì kú.’ ”

Read full chapter