Lefitiku 11:44
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
44 (A)Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀.
Read full chapter
Lefitiku 11:45
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
45 Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.
Read full chapter
Lefitiku 20:7
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
7 (A)“ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
Read full chapter
Lefitiku 20:26
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
26 (A)Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.
Read full chapter
1 Peteru 1:16
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.