Add parallel Print Page Options

Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀.

Read full chapter

10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.

Read full chapter

16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi.

Read full chapter

11 (A)Ẹ máa tẹ̀lé àpẹẹrẹ mi, gẹ́gẹ́ bí èmi náà ti ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi.

Read full chapter

Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.

Ní Berea

10 Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ.

Read full chapter

52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

Read full chapter