Add parallel Print Page Options

Jesu àti iṣẹ́ ìyanu ẹja pípa

21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. (A)Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. (B)Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

(C)Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.

(D)Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.

(E)Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” 11 Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. 12 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13 Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja. 14 (F)Èyí ni Ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Jesu fún Peteru ní iṣẹ́

15 (G)Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

16 (H)Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?”

Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17 Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?”

Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi. 18 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” 19 (I)Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

20 (J)Peteru sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó gbara le súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹni tí yóò fi ọ́ hàn?” 21 Nígbà tí Peteru rí i, ó wí fún Jesu pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”

22 (K)Jesu wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” 23 Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”

24 (L)Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí, àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25 (M)Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jesu ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́.

Jesus and the Miraculous Catch of Fish

21 Afterward Jesus appeared again to his disciples,(A) by the Sea of Galilee.[a](B) It happened this way: Simon Peter, Thomas(C) (also known as Didymus[b]), Nathanael(D) from Cana in Galilee,(E) the sons of Zebedee,(F) and two other disciples were together. “I’m going out to fish,” Simon Peter told them, and they said, “We’ll go with you.” So they went out and got into the boat, but that night they caught nothing.(G)

Early in the morning, Jesus stood on the shore, but the disciples did not realize that it was Jesus.(H)

He called out to them, “Friends, haven’t you any fish?”

“No,” they answered.

He said, “Throw your net on the right side of the boat and you will find some.” When they did, they were unable to haul the net in because of the large number of fish.(I)

Then the disciple whom Jesus loved(J) said to Peter, “It is the Lord!” As soon as Simon Peter heard him say, “It is the Lord,” he wrapped his outer garment around him (for he had taken it off) and jumped into the water. The other disciples followed in the boat, towing the net full of fish, for they were not far from shore, about a hundred yards.[c] When they landed, they saw a fire(K) of burning coals there with fish on it,(L) and some bread.

10 Jesus said to them, “Bring some of the fish you have just caught.” 11 So Simon Peter climbed back into the boat and dragged the net ashore. It was full of large fish, 153, but even with so many the net was not torn. 12 Jesus said to them, “Come and have breakfast.” None of the disciples dared ask him, “Who are you?” They knew it was the Lord. 13 Jesus came, took the bread and gave it to them, and did the same with the fish.(M) 14 This was now the third time Jesus appeared to his disciples(N) after he was raised from the dead.

Jesus Reinstates Peter

15 When they had finished eating, Jesus said to Simon Peter, “Simon son of John, do you love me more than these?”

“Yes, Lord,” he said, “you know that I love you.”(O)

Jesus said, “Feed my lambs.”(P)

16 Again Jesus said, “Simon son of John, do you love me?”

He answered, “Yes, Lord, you know that I love you.”

Jesus said, “Take care of my sheep.”(Q)

17 The third time he said to him, “Simon son of John, do you love me?”

Peter was hurt because Jesus asked him the third time, “Do you love me?”(R) He said, “Lord, you know all things;(S) you know that I love you.”

Jesus said, “Feed my sheep.(T) 18 Very truly I tell you, when you were younger you dressed yourself and went where you wanted; but when you are old you will stretch out your hands, and someone else will dress you and lead you where you do not want to go.” 19 Jesus said this to indicate the kind of death(U) by which Peter would glorify God.(V) Then he said to him, “Follow me!”(W)

20 Peter turned and saw that the disciple whom Jesus loved(X) was following them. (This was the one who had leaned back against Jesus at the supper and had said, “Lord, who is going to betray you?”)(Y) 21 When Peter saw him, he asked, “Lord, what about him?”

22 Jesus answered, “If I want him to remain alive until I return,(Z) what is that to you? You must follow me.”(AA) 23 Because of this, the rumor spread among the believers(AB) that this disciple would not die. But Jesus did not say that he would not die; he only said, “If I want him to remain alive until I return, what is that to you?”

24 This is the disciple who testifies to these things(AC) and who wrote them down. We know that his testimony is true.(AD)

25 Jesus did many other things as well.(AE) If every one of them were written down, I suppose that even the whole world would not have room for the books that would be written.

Footnotes

  1. John 21:1 Greek Tiberias
  2. John 21:2 Thomas (Aramaic) and Didymus (Greek) both mean twin.
  3. John 21:8 Or about 90 meters