Add parallel Print Page Options

Agbo kan àti olùṣọ́-àgùntàn kan

10 “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí kò bá gba ẹnu-ọ̀nà wọ inú agbo àgùntàn, ṣùgbọ́n tí ó bá gba ibòmíràn gun òkè, òun náà ni olè àti ọlọ́ṣà. (A)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ti ẹnu-ọ̀nà wọlé, Òun ni olùṣọ́ àwọn àgùntàn. Òun ni aṣọ́nà yóò ṣílẹ̀kùn fún; àwọn àgùntàn gbọ́ ohùn rẹ̀: ó sì pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ lórúkọ, ó sì ṣe amọ̀nà wọn jáde. Nígbà tí ó bá sì ti mú àwọn àgùntàn tirẹ̀ jáde, yóò síwájú wọn, àwọn àgùntàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn: nítorí tí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Wọn kò jẹ́ tọ àlejò lẹ́yìn, ṣùgbọ́n wọn a sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀: nítorí tí wọn kò mọ ohùn àlejò.” (B)Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn: ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn.

Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. (C)Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi: ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. Èmi ni ìlẹ̀kùn: bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10 Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun: èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọpọ̀.

11 (D)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (E)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (F)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. 18 (G)Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19 (H)Nítorí náà ìyapa tún wà láàrín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 20 (I)Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

21 (J)Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

Àìgbàgbọ́ àwọn Júù

22 Àkókò náà sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jerusalẹmu, ni ìgbà òtútù. 23 (K)Jesu sì ń rìn ní tẹmpili, ní ìloro Solomoni, 24 Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kristi náà, wí fún wa gbangba.”

25 (L)Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi. 26 (M)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín. 27 Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn: 28 (N)Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. 29 Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì ṣí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi. 30 (O)Ọ̀kan ni èmi àti Baba mi.”

31 (P)Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú. 32 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”

33 (Q)Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”

34 (R)Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35 Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́. 36 Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni ọmọ Ọlọ́run.’ 37 Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. 38 Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” 39 (S)Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.

40 (T)Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó. 41 Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” 42 (U)Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.

The Good Shepherd and His Sheep

10 “Very truly I tell you Pharisees, anyone who does not enter the sheep pen by the gate, but climbs in by some other way, is a thief and a robber.(A) The one who enters by the gate is the shepherd of the sheep.(B) The gatekeeper opens the gate for him, and the sheep listen to his voice.(C) He calls his own sheep by name and leads them out.(D) When he has brought out all his own, he goes on ahead of them, and his sheep follow him because they know his voice.(E) But they will never follow a stranger; in fact, they will run away from him because they do not recognize a stranger’s voice.” Jesus used this figure of speech,(F) but the Pharisees did not understand what he was telling them.(G)

Therefore Jesus said again, “Very truly I tell you, I am(H) the gate(I) for the sheep. All who have come before me(J) are thieves and robbers,(K) but the sheep have not listened to them. I am the gate; whoever enters through me will be saved.[a] They will come in and go out, and find pasture. 10 The thief comes only to steal and kill and destroy; I have come that they may have life,(L) and have it to the full.(M)

11 “I am(N) the good shepherd.(O) The good shepherd lays down his life for the sheep.(P) 12 The hired hand is not the shepherd and does not own the sheep. So when he sees the wolf coming, he abandons the sheep and runs away.(Q) Then the wolf attacks the flock and scatters it. 13 The man runs away because he is a hired hand and cares nothing for the sheep.

14 “I am the good shepherd;(R) I know my sheep(S) and my sheep know me— 15 just as the Father knows me and I know the Father(T)—and I lay down my life for the sheep.(U) 16 I have other sheep(V) that are not of this sheep pen. I must bring them also. They too will listen to my voice, and there shall be one flock(W) and one shepherd.(X) 17 The reason my Father loves me is that I lay down my life(Y)—only to take it up again. 18 No one takes it from me, but I lay it down of my own accord.(Z) I have authority to lay it down and authority to take it up again. This command I received from my Father.”(AA)

19 The Jews who heard these words were again divided.(AB) 20 Many of them said, “He is demon-possessed(AC) and raving mad.(AD) Why listen to him?”

21 But others said, “These are not the sayings of a man possessed by a demon.(AE) Can a demon open the eyes of the blind?”(AF)

Further Conflict Over Jesus’ Claims

22 Then came the Festival of Dedication[b] at Jerusalem. It was winter, 23 and Jesus was in the temple courts walking in Solomon’s Colonnade.(AG) 24 The Jews(AH) who were there gathered around him, saying, “How long will you keep us in suspense? If you are the Messiah, tell us plainly.”(AI)

25 Jesus answered, “I did tell you,(AJ) but you do not believe. The works I do in my Father’s name testify about me,(AK) 26 but you do not believe because you are not my sheep.(AL) 27 My sheep listen to my voice; I know them,(AM) and they follow me.(AN) 28 I give them eternal life,(AO) and they shall never perish;(AP) no one will snatch them out of my hand.(AQ) 29 My Father, who has given them to me,(AR) is greater than all[c];(AS) no one can snatch them out of my Father’s hand. 30 I and the Father are one.”(AT)

31 Again his Jewish opponents picked up stones to stone him,(AU) 32 but Jesus said to them, “I have shown you many good works from the Father. For which of these do you stone me?”

33 “We are not stoning you for any good work,” they replied, “but for blasphemy, because you, a mere man, claim to be God.”(AV)

34 Jesus answered them, “Is it not written in your Law,(AW) ‘I have said you are “gods”’[d]?(AX) 35 If he called them ‘gods,’ to whom the word of God(AY) came—and Scripture cannot be set aside(AZ) 36 what about the one whom the Father set apart(BA) as his very own(BB) and sent into the world?(BC) Why then do you accuse me of blasphemy because I said, ‘I am God’s Son’?(BD) 37 Do not believe me unless I do the works of my Father.(BE) 38 But if I do them, even though you do not believe me, believe the works, that you may know and understand that the Father is in me, and I in the Father.”(BF) 39 Again they tried to seize him,(BG) but he escaped their grasp.(BH)

40 Then Jesus went back across the Jordan(BI) to the place where John had been baptizing in the early days. There he stayed, 41 and many people came to him. They said, “Though John never performed a sign,(BJ) all that John said about this man was true.”(BK) 42 And in that place many believed in Jesus.(BL)

Footnotes

  1. John 10:9 Or kept safe
  2. John 10:22 That is, Hanukkah
  3. John 10:29 Many early manuscripts What my Father has given me is greater than all
  4. John 10:34 Psalm 82:6