Add parallel Print Page Options

Ìdáhùn Jobu

26 Ṣùgbọ́n Jobu sì dáhùn wí pé:

Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá,
    báwo ní ìwọ ń ṣe gbe apá ẹni tí kò ní agbára?
Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ fun ẹni tí kò ní ọgbọ́n,
    tàbí báwo òye rẹ to pọ to bẹ́ẹ̀?
Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí,
    àti ẹ̀mí ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

“Àwọn aláìlágbára ti isà òkú wárìrì,
    lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ìhòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run,
    ibi ìparun kò sí ní ibojì.
Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú,
    ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.
Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn;
    àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.
Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn,
    ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.
10 Ó fi ìdè yí omi Òkun ká,
    títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
11 Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì,
    ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.
12 Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun;
    nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.
13 Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́;
    ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.
14 Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀;
    ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!
    Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”