Add parallel Print Page Options

Ní ilé amọ̀kòkò

18 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: (A)“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun. Tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.

11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,
    ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?
    Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni
    yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?
Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,
    tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
    wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
    àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
    Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
    àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
    nǹkan ẹ̀gàn títí láé;
Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
    wọn yóò sì mi orí wọn.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
    Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
    ní ọjọ́ àjálù wọn.”

18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”

19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun

    tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
20 Ṣe kí a fi rere san búburú?
    Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,
rántí pé mo dúró níwájú rẹ,
    mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti
    yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn
    jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà
jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó
    jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn
kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
    wọn lójú ogun.
22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn
    nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun
kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́
    kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi
23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ
    gbogbo ète wọn láti pa mí,
má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.
    Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.

At the Potter’s House

18 This is the word that came to Jeremiah from the Lord: “Go down to the potter’s house, and there I will give you my message.” So I went down to the potter’s house, and I saw him working at the wheel. But the pot he was shaping from the clay was marred in his hands; so the potter formed it into another pot, shaping it as seemed best to him.

Then the word of the Lord came to me. He said, “Can I not do with you, Israel, as this potter does?” declares the Lord. “Like clay(A) in the hand of the potter, so are you in my hand,(B) Israel. If at any time I announce that a nation or kingdom is to be uprooted,(C) torn down and destroyed, and if that nation I warned repents of its evil, then I will relent(D) and not inflict on it the disaster(E) I had planned. And if at another time I announce that a nation or kingdom is to be built(F) up and planted, 10 and if it does evil(G) in my sight and does not obey me, then I will reconsider(H) the good I had intended to do for it.(I)

11 “Now therefore say to the people of Judah and those living in Jerusalem, ‘This is what the Lord says: Look! I am preparing a disaster(J) for you and devising a plan(K) against you. So turn(L) from your evil ways,(M) each one of you, and reform your ways and your actions.’(N) 12 But they will reply, ‘It’s no use.(O) We will continue with our own plans; we will all follow the stubbornness of our evil hearts.(P)’”

13 Therefore this is what the Lord says:

“Inquire among the nations:
    Who has ever heard anything like this?(Q)
A most horrible(R) thing has been done
    by Virgin(S) Israel.
14 Does the snow of Lebanon
    ever vanish from its rocky slopes?
Do its cool waters from distant sources
    ever stop flowing?[a]
15 Yet my people have forgotten(T) me;
    they burn incense(U) to worthless idols,(V)
which made them stumble(W) in their ways,
    in the ancient paths.(X)
They made them walk in byways,
    on roads not built up.(Y)
16 Their land will be an object of horror(Z)
    and of lasting scorn;(AA)
all who pass by will be appalled(AB)
    and will shake their heads.(AC)
17 Like a wind(AD) from the east,
    I will scatter them before their enemies;
I will show them my back and not my face(AE)
    in the day of their disaster.”

18 They said, “Come, let’s make plans(AF) against Jeremiah; for the teaching of the law by the priest(AG) will not cease, nor will counsel from the wise,(AH) nor the word from the prophets.(AI) So come, let’s attack him with our tongues(AJ) and pay no attention to anything he says.”

19 Listen to me, Lord;
    hear what my accusers(AK) are saying!
20 Should good be repaid with evil?(AL)
    Yet they have dug a pit(AM) for me.
Remember that I stood(AN) before you
    and spoke in their behalf(AO)
    to turn your wrath away from them.
21 So give their children over to famine;(AP)
    hand them over to the power of the sword.(AQ)
Let their wives be made childless and widows;(AR)
    let their men be put to death,
    their young men(AS) slain by the sword in battle.
22 Let a cry(AT) be heard from their houses
    when you suddenly bring invaders against them,
for they have dug a pit(AU) to capture me
    and have hidden snares(AV) for my feet.
23 But you, Lord, know
    all their plots to kill(AW) me.
Do not forgive(AX) their crimes
    or blot out their sins from your sight.
Let them be overthrown before you;
    deal with them in the time of your anger.(AY)

Footnotes

  1. Jeremiah 18:14 The meaning of the Hebrew for this sentence is uncertain.