Add parallel Print Page Options

Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ

55 (A)“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
    ẹ wá sí ibi omi;
àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
    ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
    láìsí owó àti láìdíyelé.
Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
    àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.

Read full chapter

14 (A)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

Read full chapter

48 Èmi ni oúnjẹ ìyè. 49 Àwọn baba yín jẹ manna ní aginjù, wọ́n sì kú. 50 Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú. 51 Èmi ni oúnjẹ ìyè náà tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá: bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò yè títí láéláé: oúnjẹ náà tí èmi ó sì fi fún ni fún ìyè aráyé ni ara mi.”

Read full chapter