Add parallel Print Page Options

Ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè

34 (A)Súnmọ́ tòsí,
    ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,
tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn
    jẹ́ kí ayé gbọ́,
àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.
Nítorí ìbínú Olúwa ń bẹ
    lára gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:
    o ti fi wọ́n fún pípa,
Àwọn ti a pa nínú wọn
    ni a ó sì jù sóde,
òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,
    àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn
(B)Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,
    a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,
gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,
    bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,
    àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,
    kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu,
    sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.
Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀
    a mú un sanra fún ọ̀rá,
àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
    fún ọ̀rá ìwé àgbò—
nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bosra,
    àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu.
Àti àwọn àgbáǹréré yóò
    ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
    pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
    a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá.

Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni,
    àti ọdún ìsanpadà,
    nítorí ọ̀ràn Sioni.
(C)Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,
    àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,
    ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.
10 A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán,
    èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:
yóò dahoro láti ìran dé ìran,
    kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé
àti láéláé.
11 Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín,
    àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu
    okùn ìwọ̀n ìparun
    àti òkúta òfo.
12 Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀
    ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀
tiwọn ó pè wá sí ìjọba,
    gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán.
13 Ẹ̀gún yóò sì hù jáde
    nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí,
ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀.
    Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá
    àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.
14 Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé,
àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀,
    iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú,
    yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.
15 Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀,
    yóò yé, yóò sì pa,
yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:
    àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú,
    olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.

16 Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa, ẹ sì kà á:

Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀,
    kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù:
nítorí Olúwa ti pàṣẹ
    ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ
    Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.
17 Ó ti di ìbò fún wọn,
    ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn
nípa títa okùn,
    wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,
láti ìran dé ìran
    ni wọn ó máa gbé inú rẹ̀.

Ọjọ́ ẹ̀san àti ìràpadà Ọlọ́run

63 (A)Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá,
    ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?
Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,
    tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?

    “Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo
    tí ó ní ipa láti gbàlà.”

Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa
    gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

(B)“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;
    láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.
Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi
    mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi
ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,
    mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.
Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi
    àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé
Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.
    Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;
nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi
    àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.
Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;
    nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu
    mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”

Read full chapter

Àsọtẹ́lẹ̀ Ní ti Edomu

(A)Nípa Edomu:

Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani?
    Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?
    Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?
Yípadà kí o sálọ, sápamọ́ sínú ihò,
    ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,
nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,
    ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.
Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;
    ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?
Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní
    kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?
10 Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,
    èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,
nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.
    Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti
àwọn ará ilé rẹ yóò parun.
    Wọn kò sì ní sí mọ́.
11 Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀
    èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.
    Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”

12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. 13 Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

14 Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
    A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé,
    Ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.

15 “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di
    kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo;
    ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.
16 Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú
    ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;
ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta,
    tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga
síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;
    láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”
    ni Olúwa wí.
17 “Edomu yóò di ahoro
    gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì
    fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ
18 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu
    àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú
tí ó wà ní àyíká rẹ,”
    Olúwa wí.
“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;
    kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

19 “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
    Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
    Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí
    Olúwa ní fún Edomu, ohun tí
ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani.
    Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde.
    Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21 Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn,
    a ó gbọ́ igbe wọn
    ní Òkun pupa.
22 Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,
    yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra.
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun
    Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.

Read full chapter

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Edomu

12 (A)“Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí pé: ‘Nítorí pé Edomu gbẹ̀san lára ilé Juda, ó sì jẹ̀bi gidigidi nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, 13 nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Edomu èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti Temani dé Dedani yóò ti ipa idà ṣubú. 14 Èmi yóò gbẹ̀san lára Edomu láti ọwọ́ àwọn ènìyàn mi Israẹli, wọn sì ṣe sí Edomu gẹ́gẹ́ bí ìbínú àti ìrunú mi: wọn yóò mọ̀ ìgbẹ̀san mi ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Read full chapter

Àsọtẹ́lẹ̀ si Edomu

35 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn kọjú sí òkè Seiri; sọtẹ́lẹ̀ sí i Kí o sì sọ wí pé: ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmí lòdì sí ọ, òkè Seiri, Èmi yóò sì na ọwọ́ mi síta ní ìlòdì sí ọ, èmi yóò sì mú kí ó di ahoro. Èmi yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

“ ‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Israẹli lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó, nítorí náà bi mo ti wà láààyè, ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ́n ìgbà tí ìwọ kò ti kórìíra ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ. Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ: àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárín àwọn òkè rẹ. Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé; Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

10 “ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀, 11 nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárín wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ. 12 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti gbọ́ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Israẹli náà. Ìwọ wí pé, “A sọ wọ́n di ahoro, a sì fi wọ́n fún wa láti run.” 13 Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ. 14 Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro 15 Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Israẹli di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Seiri, ìwọ àti gbogbo ará Edomu. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa.’ ”

11 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Edomu,
    àní nítorí mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí òhun fi idà lépa arákùnrin rẹ̀,
    Ó sì gbé gbogbo àánú sọnù
ìbínú rẹ̀ sì ń faniya títí
    ó sì pa ìbínú rẹ̀ bí èéfín mọ́
12 Èmi yóò rán iná sí orí Temani
    Tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”

Read full chapter

Ọlọ́run fẹ́ràn Jakọbu, o sì kórìíra Esau

(A)(B) “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni Olúwa wí.

“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’

“Esau kì í ha ṣe arákùnrin Jakọbu bí?” ni Olúwa wí. “Síbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jakọbu, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akátá aginjù.”

Edomu lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.”

Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní ilẹ̀ búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú Olúwa. Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni Olúwa, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Israẹli.’

Read full chapter