Heberu 3:7-11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìkìlọ̀ fún aláìgbàgbọ́
7 (A)Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,
bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù:
9 Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,
tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,
mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;
wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
Heberu 4:3-11
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
3 (A)Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí,
“Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé. 4 (B)Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.” 5 (C)Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”
6 Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìhìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn: 7 (D)Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú,
“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”
8 Nítorí, ìbá ṣe pé Joṣua tí fún wọn ní ìsinmi, òun kì bá tí sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìsinmi mìíràn lẹ́yìn náà, 9 nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. 10 (E)Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀. 11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.