Add parallel Print Page Options

Ìkún omi

(A)Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”

(B)Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.

Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́. Nítorí náà, Olúwa wí pé, “Èmi yóò pa ènìyàn tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀, ènìyàn àti ẹranko, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí inú mi bàjẹ́ pé mo ti dá wọn.” Ṣùgbọ́n, Noa rí ojúrere Olúwa.

(C)Wọ̀nyí ni ìtàn Noa.

Noa nìkan ni ó jẹ́ olóòótọ́ ènìyàn àti ẹni tí ó pé ní ìgbà ayé rẹ̀, ó sì fi òtítọ́ bá Ọlọ́run rìn. 10 Noa sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣemu, Hamu àti Jafeti.

11 Ayé sì kún fún ìbàjẹ́ gidigidi ní ojú Ọlọ́run, ó sì kún fún ìwà ipá pẹ̀lú. 12 Ọlọ́run sì rí bí ayé ti bàjẹ́ tó, nítorí àwọn ènìyàn inú ayé ti bá ara wọn jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà wọn. 13 Ọlọ́run sì wí fún Noa pé, “Èmi yóò pa gbogbo ènìyàn run, nítorí ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá nípasẹ̀ wọn. Èmi yóò pa wọ́n run àti ayé pẹ̀lú. 14 Nítorí náà fi igi ọ̀mọ̀ kan ọkọ̀, kí o sì yọ yàrá sí inú rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà-ilẹ̀ rẹ́ ẹ tinú-tẹ̀yìn. 15 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe kan ọkọ̀ náà: Gígùn rẹ̀ ní òró yóò jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ yóò jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, nígbà tí gíga rẹ̀ yóò jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. 16 Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìsàlẹ̀, ọ̀kan ní àárín àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu-ọ̀nà ọkọ̀ náà sí. 17 Èmi yóò mú ìkún omi wá sí ayé láti pa gbogbo ohun ẹlẹ́mìí run lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè ní inú. Gbogbo ohun tí ó wà nínú ayé yóò parun. 18 Ṣùgbọ́n èmi ó dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì wọ ọkọ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú aya rẹ. 19 Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀, kí wọn le wà láààyè pẹ̀lú rẹ. 20 Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjì méjì, kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láààyè. 21 Mú onírúurú oúnjẹ wá sínú ọkọ̀, kí o pa wọ́n mọ́ fún jíjẹ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà nínú ọkọ̀ àti ènìyàn àti ẹranko.”

22 (D)Noa sì ṣe ohun gbogbo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un.

Wickedness in the World

When human beings began to increase in number on the earth(A) and daughters were born to them, the sons of God(B) saw that the daughters(C) of humans were beautiful,(D) and they married(E) any of them they chose. Then the Lord said, “My Spirit(F) will not contend with[a] humans forever,(G) for they are mortal[b];(H) their days will be a hundred and twenty years.”

The Nephilim(I) were on the earth in those days—and also afterward—when the sons of God went to the daughters of humans(J) and had children by them. They were the heroes of old, men of renown.(K)

The Lord saw how great the wickedness of the human race had become on the earth,(L) and that every inclination of the thoughts of the human heart was only evil all the time.(M) The Lord regretted(N) that he had made human beings on the earth, and his heart was deeply troubled. So the Lord said, “I will wipe from the face of the earth(O) the human race I have created—and with them the animals, the birds and the creatures that move along the ground—for I regret that I have made them.(P) But Noah(Q) found favor in the eyes of the Lord.(R)

Noah and the Flood

This is the account(S) of Noah and his family.

Noah was a righteous man, blameless(T) among the people of his time,(U) and he walked faithfully with God.(V) 10 Noah had three sons: Shem,(W) Ham and Japheth.(X)

11 Now the earth was corrupt(Y) in God’s sight and was full of violence.(Z) 12 God saw how corrupt(AA) the earth had become, for all the people on earth had corrupted their ways.(AB) 13 So God said to Noah, “I am going to put an end to all people, for the earth is filled with violence because of them. I am surely going to destroy(AC) both them and the earth.(AD) 14 So make yourself an ark of cypress[c] wood;(AE) make rooms in it and coat it with pitch(AF) inside and out. 15 This is how you are to build it: The ark is to be three hundred cubits long, fifty cubits wide and thirty cubits high.[d] 16 Make a roof for it, leaving below the roof an opening one cubit[e] high all around.[f] Put a door in the side of the ark and make lower, middle and upper decks. 17 I am going to bring floodwaters(AG) on the earth to destroy all life under the heavens, every creature that has the breath of life in it. Everything on earth will perish.(AH) 18 But I will establish my covenant with you,(AI) and you will enter the ark(AJ)—you and your sons and your wife and your sons’ wives with you. 19 You are to bring into the ark two of all living creatures, male and female, to keep them alive with you.(AK) 20 Two(AL) of every kind of bird, of every kind of animal and of every kind(AM) of creature that moves along the ground will come to you to be kept alive.(AN) 21 You are to take every kind of food that is to be eaten and store it away as food for you and for them.”

22 Noah did everything just as God commanded him.(AO)

Footnotes

  1. Genesis 6:3 Or My spirit will not remain in
  2. Genesis 6:3 Or corrupt
  3. Genesis 6:14 The meaning of the Hebrew for this word is uncertain.
  4. Genesis 6:15 That is, about 450 feet long, 75 feet wide and 45 feet high or about 135 meters long, 23 meters wide and 14 meters high
  5. Genesis 6:16 That is, about 18 inches or about 45 centimeters
  6. Genesis 6:16 The meaning of the Hebrew for this clause is uncertain.