Add parallel Print Page Options

27 (A)(B) Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,
    ní àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá a,
    akọ àti abo ni Ó dá wọn.

Read full chapter

28 Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú Òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.”

Read full chapter

Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’

Read full chapter

(A)Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo.

Read full chapter