Add parallel Print Page Options

Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
    àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
    òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
    ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
    ni Olúwa Olódùmarè wí
Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
    nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
    kò í tí ì mọ̀.
10 Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
    àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
    nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
    ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
    ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

11 “ ‘Nítorí èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Idà ọba Babeli
    yóò wá sí orí rẹ,
12 Èmi yóò mú kí ìjọ ènìyàn rẹ kí ó
    tí ipa idà àwọn alágbára ènìyàn ṣubú
àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú jùlọ.
    Wọn yóò tú ìgbéraga Ejibiti ká,
    gbogbo ìjọ rẹ ní a yóò dá ojú wọn bolẹ̀.
13 Gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ ni èmi yóò parun
    ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi
kì i ṣe ẹsẹ̀ ènìyàn ní yóò tẹ ibẹ̀
    ẹsẹ̀ ẹran ọ̀sìn kì yóò sì mú kí ibẹ̀ ni ẹrọ̀fọ̀.
14 Lẹ́yìn náà èmi yóò mú kí omi rẹ̀ tòrò
    kí àwọn odò rẹ̀ kí o sàn bí epo,
    ni Olúwa Olódùmarè wí.
15 Nígbà tí mo bá sọ Ejibiti di ahoro,
    tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.
Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,
    nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

16 “Èyí yìí ni ẹkún tí a yóò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè yóò sun ún; nítorí Ejibiti àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

17 Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá: 18 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún lórí Ejibiti kí o sì ránṣẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀-èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò. 19 Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ́ ìwọ ní ojúrere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárín àwọn aláìkọlà náà.’ 20 Wọn yóò ṣubú láàrín àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Ejibiti kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.

Read full chapter