Add parallel Print Page Options

20 (A)Ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan pákó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀, 22 pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì tí ó kọjú sí ara wọn. Wọ́n ṣe gbogbo pákó àgọ́ náà bí èyí. 23 Ó sì ṣe ogún pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà. 24 Ó sì ṣe ogójì (40) fàdákà ihò ìtẹ̀bọ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ wọn ìtẹ̀bọ̀ méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀. 25 Fún ìhà kejì, ìhà àríwá àgọ́ náà, wọ́n ṣe ogún pákó 26 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 27 Ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 28 pákó méjì ni ìwọ ó ṣe fún igun àgọ́ náà ní ìhà ẹ̀yìn. 29 Ní igun méjèèjì yìí, pákó méjì ni ó wà níbẹ̀ láti ìdí dé orí rẹ̀ wọ́n sì kó wọ́n sí òrùka kan; méjèèjì rí bákan náà. 30 Wọ́n ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

31 Ó sì ṣe ọ̀pá igi kasia márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 32 márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìkangun àgọ́ náà. 33 Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárín tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárín àwọn pákó náà. 34 Ó sì bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùka wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

Read full chapter