Add parallel Print Page Options

Besaleli àti Oholiabu

30 (A)Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 31 Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà 32 Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, 33 láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. 35 Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe. 36 Besaleli, Oholiabu àti olúkúlùkù ọlọ́gbọ́n ẹni tí Olúwa tí fún ní ọgbọ́n àti òye láti mọ bí a ti í ṣe gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ ni kí wọn ṣe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”