Add parallel Print Page Options

31 Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32 (A)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”

33 Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34 Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35 Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.

Read full chapter

Mose bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn

11 (A)Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe láàrín wọn? 12 Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”

13 Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn. 14 Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru. 15 Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé, 16 ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú aginjù yìí.’

17 “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: 18 Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ 19 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.”

20 Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ; 21 Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa. 22 (B)Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, 23 Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. 24 Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀. 25 Níwọ́n ìgbà tí àwọn ará Amaleki àti àwọn ará Kenaani ń gbé ní Àfonífojì, ẹ yípadà lọ́la kí ẹ sì dojúkọ aginjù lọ́nà Òkun Pupa.”

Read full chapter