Add parallel Print Page Options

Ọ̀pá fìtílà

31 (A)“Ìwọ ó sì ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, ṣe ọ̀pá fìtílà kan, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 32 Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 33 Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà. 34 Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 35 Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 36 Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.

37 “Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀. 38 Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà. 39 Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí.

Read full chapter