Add parallel Print Page Options

Tábìlì

23 (A)“Fi igi kasia kan tábìlì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga. 24 Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 25 Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 26 Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 27 Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà fún ibi ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà. 28 Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 29 Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde.

Read full chapter