Add parallel Print Page Options

12 (A)(B) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

13 (C)(D) Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.

14 (E)Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

15 (F)Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

16 (G)Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

Read full chapter

16 (A)(B) Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún ọ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́, àti kí ó lè dára fún ọ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

17 (C)(D) Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.

18 Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

19 Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

20 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

Read full chapter

(A)Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”

Read full chapter

11 (A)Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.

Read full chapter